Sunday, October 31, 2021

EYONU ATUDE

EYONU ATUDE TODAJU

Eleyi ni ose atude tohun mu ide olojo pipe ja kuro Lara eda,ti ona yio si la fun Eniyan ninu Aye
Ewe iyalode funfun meta,eye ounbe Kan,
Ewe ajeobale eyo meta,eye ounbe Kan
Ewe akoko eyo meta eye ounbe Kan
Ao mu ewe akoko eyokan pelu ewe ajeobale kan pelu ewe iyalode kan pelu eye ounbe Kan ao lo papo,ao Koo lose iwe eeekan pere,ao fisi Ori eepo obo kekere kan,ao tun se bee Lona keji,aotun sebe Lona keta
Tobadi agogo mejila osan,ao we ose alakoko,pelu Kanhinkanhin tuntun ao bo mole,ao we eleekeji ni ago meta osan ojo naa,aotun we eleeketa ni ago mefa irole ojo nan,yen,ao bo Kanhinkanhin re mole
Sugbon ojo ti aba we awon ose yi agbodo losi ibi kankan lati ago meje aro ojo nan di ago merin idaji ojo keji

Friday, October 29, 2021

IWOSAN EGBO ADAAJINA

 Igbe ewure ama sa kogbe dada ao lo kùnà dada ao ro pamo sí inú ike kan, ewe omundo lápá lápá funfun ama Gun mọn ọsẹ dudu ewe làpálàpá funfun yii la ma ja fi se keyinkeyin ao ma bù ọsẹ sí orí ewe naa ama fi fo egbo naa ao ma wa da eyiti a lo pamo yen ao ma da sí ojú egbo naa 


Pelu ase Olohun egbo naa yíò pa oju dé pada 


Bẹ l'ao se ma lo ọsẹ ati powder náà lè meji lose 

Tuesday, October 26, 2021

OSE ASINA ATI ISEGUN OTA< ATI AKOYA

 ejeki a wa epo obo die, atajosi die, isu ogirisako die, eso aworonso die ao gun papo ti yio kuna dada ao po lose dudu ao wa te ose naa ni ifa ejiogbe ninu igba tabi ike funfun ao bu iyepe oju titi ona motor si oju odu kokan ti a te si ori ose yen ao wa de ao gbe pamo fun 8 days leyin 8 days ao ma bu oju odu kokan we lojojumo fun 8 days ao bere bubu ose naa lati isale ifa ejiogbe yen titi ao fi we tan

Saturday, October 23, 2021

AWURE EYONU AWON AGBA

 ELEYI NI AWURE EYONU AWON AGBA


Ewe orijin tutu, ewe iyalode funfun tutu, ori olongbo kan, ao gun won kuna dada ao ti yo epo ori ati adin sinu orun ao fi po ose na dada ao wa ko sinu ike funfun ao ma fi we ni idaji bi agogo marun aro ki ojo to yo rara lao ti fi we. Eyonu asina todaju ni




Thursday, October 21, 2021

OSHOLE APEDE

 OSHOLE APEDE (AWORO)

Ewe awoyoyo tutu, ewe awerepepe oojo, ewe adagudu ojoo, ekute ile toje ako ao gunn won papo kùnà dada ao po mo ori ao wa ko sinu konjo kekere kan ao fi ideri re dé ao gbe sinu aso funfun ao we lowu funfun dada ao wa ri mo enu ona ilé ìtajà pẹlu adua dada


EWE ADAGUDU




EWE INABO TABI AHOYOYO


EWE SAWEREPEPE



Wednesday, October 20, 2021

ASIRI TI A NFI NGBA ORE WA PADA

 ELEYI NI ASIRI TI A NFI NGBA ORE WA PADA LOWO AWON ALA IRU EDA.

Ejeki awa ewe gbegbe tutu, ewe Imi Esu tutu ao gun kuna dada pẹlu epo obo ao poo ose dudu tobajepe obinrin lọfẹ lo iṣẹ yìí wo koko lo osun kùnà dada ao da sinu ike tabi igba ti a fe ko ọsẹ yìí sí ao wa ko ọsẹ le lori toba jepe okunrin lọfẹ lo ao ko ọsẹ yen sinu igba olomori kan tabi ike fufun kan ao wa ki ikode ni ori ọsẹ náà ao ma fi wẹ lararo odaju.




EWE GBEGBE




Dr Mutiu Olatiboye

Monday, October 18, 2021

ASEJE ASIRI BIBO KIAKIA

 ASEJE ASIRI BIBO KIAKIA FUN ENITI O JE GBESE

Ejeki a wa ewe Afaimonikonimonra tabi ewe akonimonra tabi ewe Sinkinmini tutu tàbí gbigbe ao gun kuna dada tabi kalo kùnà dada ao wa èyin adiẹ òróró meta toba mọn dada ao fo eyin naa sinu cup kan ao wa da ewe talo yen si ao po papo dada ao fi iyo isebe sí ao wa po papo dada ao fi Ororo din ẹyin naa je ninu isasun tuntun kan.


Ti aba ti din tan toba tutu ao gbe sori osuka ao wa se adua sí wipe


Oso, aje, ọmọde ati agba ki binu titi ki won fi eyin adìe leko soja. Ki asiri emi Lagbaja omo lagbaja bo Si ìyè owo bayi bayi.


Ao je eyin naa odaju


ELEYI NI EWE AKONIMONRA






Dr Mutiu Olatiboye



Sunday, October 17, 2021

ASIRI TI A MA NFI NGBA OGO WA PADA

JU OGO MI SILE


 Ejeki awa ewé túdè ati egbo túdè, epo obo ti o fe to atelewo eniti o fe se iṣẹ náà ti aba fe se fún enia ama so fun ẹni náà wipe ko print atelewo alafia ẹni náà sinu iwe funfun kan ao ma wa le iwe naa mo oju epo obo naa ti ibi atelewo yíò siju soke lori epo obo naa.


Leyin naa ama wa Gun epo obo naa pelu photo atelewo eni naa papo mo ra won dada ti o ba jepe ayé wà fún wa ao le fi bi black biro yaa aworan owo wa Si ori epo obo naa ao wa Gun won papo mo ewe ati egbo túdè. Ejeki a po mo Ose dudu ao ko sinu igba olomori kan tabi ike fufun kan ao wa fi abere ọpọro meje fún Obìnrin, 9 fún Ọkùnrin ao fi abe re naa Gun ori ọsẹ yen kakiri ao wa fi ideri igba náà dé ao gbe pamo fún dede iye ọjọ ori eniti o fe lo. Ti eni naa ba jẹ 30 years 30 days lama fi gbe pamo. Leyin ojo naa ao ma bù ọsẹ náà wẹ laro tabi lale. Odaju..


ELEYI NI EWE TUDE 




Dr Mutiu Olatiboye





OWOH TODAJU

 Ewe ẹyìn olobe tutu ao tu tegbo tegbo  ao wa Gun kùnà dada ao wa èyin òpè topon dada iyekiye ao. Ti abawo ori èyin òpè ao ri wipe ayé kan nibe ma dudu ibe lama rẹ ti yíò po diẹ, ao Gun papo mo ewe ẹyìn olobe yen ao wa ma di ni ikobere iyekiye pẹlu eyo atare k'ọkan ao ma fi sara odaju dada

ÌWÒSÀN ÌKỌ

 Eleyi ni iwosan iko todaju dada.


Ejeki a wa orogbo gbigbe, etu ibon original, obutoyo, odindi atare kan, aolo gbogbo rẹ papo  kunna daada, aoda sinu oyin gidi, 



LILO RE

Ao ma la laro ati lale patapata ti aba fe sun ao ma la diedie

Saturday, October 16, 2021

OWO (RESPECT) TODAJU

 Owo je unkan pataki ti o ye ki a ma mun rin lekokan tabi nigba gbogbo, ninu ogun to kereju fun omo Yoruba lati ma fi si ara o yeki Owo je okan ni ibe. Ti owo ba wa ni ara, eleyi a ma le aburu jina si iru eniti owo ba wa lara re kuro. Lotoo Olohun oba ni olu dabobo eda re to da, Olohun ki si fi eda re sile. Ninu ki ase ma se adua ki ama se ri aburu ara owo ni owaa, Owo wa porisirisi gegebi a se mo, owo alaseje wa, oni gbere wa ati bebelo. ninu eyiti mo fe salaye fun wa lori website yii ni owo ohunkohun.



Ejeki awa agbado boromo, agbado yii ni agbado ti o ma npon bi eje bayi. ti aba de odo awon elewe omo ejeki a so fun won wipe a fe ra agbado boromon, ejeki a gun agbado yii ki o kuna dada, leyinna a lo wa ewe koropo ti a mo si efo onise ti biological name re si nje Rattle box, rattle pea tabi Crotalaria retusa. tutu ewe yii ni a fe lo ao ko sinu odo ao wa gun ao fi owo bu iyo isebe si, ao tun fi owo bu epo pupa si, akiyesi owo ni ao ma fi bu awon unkan yii si o ki se sibi tabi unkan miran, owo ni ao ma fi bu si. ao wa gun papo ko kuna dada. ao wa ewe eran eyiti won ma nfi npon eko jije ao ko ewe ti a gun yii si die, ao wa ko oruka elelo iyekiye si ori eyiti a ko sinu ewe eran yen ao tun wa ko ewe ti agun yen bo ori oruka yen dada, ao wa pon ewe yen bi eni ti o pon eko. ao fi bi copper wire di daadaa, ao wa lo da ina edu ti o ke dada ao gbe ogun yii sinu ina ko jona tan pata pata. ti o ba ti jona tan ao fi unkan ko gbogbo oruka yen pata kuro ao sa si inu ategun. 






LILO RE

Ti aba ti fe jade lo si ibikan ejeki ama ki oruka yii bowo pelu gbolohun wipe


sefo sefo kan ki sefo onise

yaka yaka kan ki yaka ago

towo bepo towo boyo ki towo bona

ki aburu kankan ma se se emi lagbaja omo lagbaja loni

etc

odaju pupo


Dr Mutiu Olatiboye

ABIWERE FUN ALABOYUN

ABIWERE TODAJU

Ao wa eresile ewe bomubomu to ba po dada ao sa koigbe dada ao wa lo kunna dada ao ro pamo sibikan, ti obinrin bati ri omira e je kio fi omi toloworo lo die ninu ogun tia ro pamo yii, pelu ase Olohun yio bi omo naa pelu irorun

Dr Mutiu Olatiboye

Friday, October 15, 2021

EYONU TODAJU

 EYONU AWON AGBA.

Ejeki awa Eku asin gbigbe meje, oga gbigbe meje, eye ega ako tabi abo meje, odidi atare meje, aoko won sinu agbada tuntun, aoko ewe orijin oojo bo mole ninu agbada, aojo, aolo kunna daadaa, aoma fi foko tutu mu laraaro

IMUNLE AWON AGBA

 

IFA IMUNLE TODAJU DADA


Ejeki a wa ako alangba meje to ba pe dada, ao jo pelu odindin atare nla kan, ejeki a lo kuna dada ao wa po mo ose dudu ao ko ose yii sinu igba olomori kan, leyin naa ejeki a jo ewe ewuro Gbawoniyi ti a tun mo si ewe ewuro ojoo pelu odindi atare kan ao lo kuna dada ejeki a ro sinu ado ato ki awa ran ado ato yii laso funfun ni gbogbo ara, ejeki a gbe ohun naa pamo si aye kan. ejeki a jo abo alangba nikan pelu odindin atare kan ao lo kuna ao ro sinu ado ide kekere kan oni ese meta. to si ni ideri.

ao wa ki idi ado ide yii bonu ose inu igba naa ti yio kan isale igba naa dada. leyin naa ejeki a gbe pamo ti o ba di ojo thursday ejei a wa gbe eyiti ajo ti aro sinu ado ato yen ki a fi la epo pupa ni igbati aba ti fe sun ao gbodo jade mon rara o. leyin igba naa ti o bati di aro kutukutu ojo friday ao si ideri igba eyiti ose wa ninu re ao si enu ado ide yen naa sile ao bu ose ibe ao lo fi we. be lao se ma lo ti aba fe lo.


AKIYESI

ni aro ojo friday ti aba si igbayi pelu ideri ado ide yen sile, ao gbodo de mon pada titi ile ojo naa yio fi su ti ile ba su ao wa fi ideri ado ati ideri igba yen de pada. odaju

Dr Mutiu Olatiboye