Friday, October 15, 2021

IMUNLE AWON AGBA

 

IFA IMUNLE TODAJU DADA


Ejeki a wa ako alangba meje to ba pe dada, ao jo pelu odindin atare nla kan, ejeki a lo kuna dada ao wa po mo ose dudu ao ko ose yii sinu igba olomori kan, leyin naa ejeki a jo ewe ewuro Gbawoniyi ti a tun mo si ewe ewuro ojoo pelu odindi atare kan ao lo kuna dada ejeki a ro sinu ado ato ki awa ran ado ato yii laso funfun ni gbogbo ara, ejeki a gbe ohun naa pamo si aye kan. ejeki a jo abo alangba nikan pelu odindin atare kan ao lo kuna ao ro sinu ado ide kekere kan oni ese meta. to si ni ideri.

ao wa ki idi ado ide yii bonu ose inu igba naa ti yio kan isale igba naa dada. leyin naa ejeki a gbe pamo ti o ba di ojo thursday ejei a wa gbe eyiti ajo ti aro sinu ado ato yen ki a fi la epo pupa ni igbati aba ti fe sun ao gbodo jade mon rara o. leyin igba naa ti o bati di aro kutukutu ojo friday ao si ideri igba eyiti ose wa ninu re ao si enu ado ide yen naa sile ao bu ose ibe ao lo fi we. be lao se ma lo ti aba fe lo.


AKIYESI

ni aro ojo friday ti aba si igbayi pelu ideri ado ide yen sile, ao gbodo de mon pada titi ile ojo naa yio fi su ti ile ba su ao wa fi ideri ado ati ideri igba yen de pada. odaju

Dr Mutiu Olatiboye

No comments:

Post a Comment